Ezekiel 3:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn bí mo bá bá ọ sọ̀rọ̀ tán, n óo là ọ́ lóhùn, o óo sì sọ ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun bá sọ fún wọn. Ẹni tí ó bá fẹ́, kí ó gbọ́, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó má gbọ́, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni ìdílé wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nigbati mo ba bá ọ sọ̀rọ, emi o ya ẹnu rẹ, iwọ o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹniti o gbọ́, jẹ ki o gbọ́; ẹniti o kọ̀, jẹ ki o kọ̀ nitori ọlọ̀tẹ ile ni nwọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nígbà tí èmi bá bá ọ sọ̀rọ̀, Èmi yóò sí ọ lẹ́nu, ìwọ yóò sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run wí.’ Ẹni tó bá fẹ́ kí ó gbọ́, ẹni tó bá fẹ́ kọ̀, kó kọ̀ nítorí ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n.