Ezekiel 3:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó tún sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, lọ bá àwọn ọmọ Israẹli kí o sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, Lọ, tọ̀ ile Israeli lọ ki o si fi ọ̀rọ mi ba wọn sọrọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì tún sọ fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, lọ ni ìsinsinyìí bámi sọ ọ̀rọ̀ mi fún ìle Ísírẹ́lì.