Ezekiel 3:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N kò rán ọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń sọ èdè mìíràn tí yóo ṣòro fún ọ láti gbọ́. Dájúdájú, bí ó bá jẹ́ irú wọn ni mo rán ọ sí, wọn ìbá gbọ́ tìrẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki iṣe si ọ̀pọlọpọ enia ède ajeji, ati ède sisọrọ, ọ̀rọ ẹniti iwọ kò le gbọ́. Nitotọ emi iba rán ọ si wọn, nwọn iba gbọ́ tirẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
kì í ṣe sí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó ń sọ àjèjì èdè tàbí tí èdè wọn ṣòro láti gbọ́, àwọn tí ọ̀rọ̀ wọn le fún ọ láti gbọ́ yé. Dájúdájú bí mo bá rán ọ sí wọn, wọn ì bá sì fetí sílẹ̀ sí ọ.