Ezekiel 30:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo mú kí odò Naili gbẹ, n óo ta ilẹ̀ náà fún àwọn eniyan burúkú; n óo sì jẹ́ kí àwọn àjèjì sọ ilẹ̀ náà ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ di ahoro. Èmi OLUWA ní mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o mu gbogbo odò wọn gbẹ, emi o si tà ilẹ na si ọwọ́ awọn enia buburu; emi o si ti ipa ọwọ́ awọn alejo sọ ilẹ wọn di ahoro, ati ẹkún rẹ̀: Emi Oluwa li o ti sọ ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò mú kí àwọn odò Náílì gbẹ Èmi yóò sì ta ilẹ náà fún àwọn ènìyàn búburú: láti ọwọ́ àwọn àjòjì ènìyàn Èmi yóò jẹ́ kí ilẹ̀ náà àti gbogbo ohun tí ó wá nínú rẹ ṣòfò. Èmi OLÚWA ni ó ti sọ ọ́.