Ezekiel 30:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun ní, “N óo fọ́ àwọn ère tí ó wà ní Memfisi, n óo sì pa wọ́n run. Kò ní sí ọba ní ilẹ̀ Ijipti mọ́, n óo jẹ́ kí ìbẹ̀rù dé bá ilẹ̀ Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o pa awọn oriṣa run pẹlu, emi o si jẹ ki ere wọn tán ni Nofi; kì yio si si ọmọ alade kan ni ilẹ Egipti mọ́: emi o si fi ẹ̀ru si ilẹ Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Báyìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí: “ ‘Èmi yóò pa àwọn òrìṣà run Èmi yóò sì mú kí òpin dé bá ère òrìṣà gbígbẹ́ ni Nófì kò ní sí ọmọ aládé mọ́ ní Éjíbítì, Èmi yóò mú kí ìbẹ̀rù gba gbogbo ilẹ̀ náà.