Ezekiel 30:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ojú ọjọ́ yóo ṣókùnkùn ní Tehafinehesi nígbà tí mo bá ṣẹ́ ọ̀pá ìjọba Ijipti, agbára tí ó ń gbéraga sí yóo sì dópin. Ìkùukùu óo bò ó mọ́lẹ̀; wọn óo sì kó àwọn ọmọbinrin rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọjọ yio si ṣõkun ni Tehafnehesi, nigbati emi bá dá àjaga ọrùn Egipti nibẹ: ọṣọ́ agbara rẹ̀ yio tán ninu rẹ̀: bi o ṣe tirẹ̀ ni, ikũkũ yio bò on, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin yio lọ si igbèkun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ojú ọjọ́ yóò ṣókùnkùn ní Tápárebì nígbà tí mo bá já àjàgà Éjíbítì kúrò; níbẹ̀ agbára iyì rẹ̀ yóò dópin wọn yóò fi ìkùukùu bò ó àwọn abúlé rẹ ní wọn yóò lọ sí ìgbèkùn.