Ezekiel 30:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, mo lòdì sí Farao, ọba Ijipti. Èmi OLUWA Ọlọrun ní mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo ṣẹ́ ẹ ní apá mejeeji: ati èyí tó ṣì lágbára, ati èyí tí ó ti ṣẹ́ tẹ́lẹ̀; n óo sì gbọn idà bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; kiyesi i, emi dojukọ Farao ọba Egipti, emi o si ṣẹ́ apá rẹ̀, eyi ti o le, ati eyiti o ṣẹ́; emi o si jẹ ki idà bọ́ kuro li ọwọ́ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, báyìí ní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi lòdì sí Fáráò Ọba Éjíbítì. Èmi yóò sẹ́ apá rẹ̀ méjèèjì, èyí tí ó dára àti èyí tí a ti ṣẹ́ pẹ̀lú, yóò sì mú kí idà bọ́ sọnù ní ọwọ́ rẹ̀.