Ezekiel 30:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo fún ọba Babiloni lágbára, ṣugbọn ọwọ́ Farao yóo rọ. Wọn yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA. Nígbà tí mo bá fi idà mi lé ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo fa idà náà yọ yóo gbógun ti ilẹ̀ Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn emi o mu apá ọba Babiloni le, apá Farao yio si rọ; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi o ba fi idà mi si ọwọ́ ọba Babiloni, ki o le ba nà a sori ilẹ Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò mú kí apá Ọba Bábílónì lé, ṣùgbọ́n apá Fáráò yóò sì rọ. Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA, nígbà tí mo bá mú idà mi sí ọwọ́ Ọba Bábílónì yóò sì fí idà náà kọlu Éjíbítì.