Ezekiel 30:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ogun yóo jà ní Ijipti, ìrora yóo sì bá Etiopia. Nígbà tí ọpọlọpọ òkú bá sùn ní Ijipti, tí a kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ, tí a sì wó ìpìlẹ̀ rẹ̀ lulẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Idà yio si wá sori Egipti, irora nla yio wà ni Etiopia, nigbati awọn ti a pa yio ṣubu ni Egipti, nwọn o si mu ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ lọ kuro, ipilẹ rẹ̀ yio si wó lulẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Idà yóò wá sórí Éjíbítì ìrora ńlá yóò sì wá sórí Kúṣì Nígbà tí àwọn tí a pa yóò subú ní Éjíbítì wọn yóò kò ọrọ̀ rẹ̀ lọ ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóò sì wó lulẹ̀.