Ezekiel 30:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Àwọn tí ń ran Ijipti lọ́wọ́ yóo ṣubú, ìgbéraga rẹ̀ yóo sì wálẹ̀; láti Migidoli títí dé Siene, wọn ó kú ikú ogun láàrin ìlú. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi; Awọn pẹlu ti nwọn gbe Egipti ró yio ṣubu; ati igberaga agbara rẹ̀ yio sọkalẹ: lati Migdoli lọ de Siene ni nwọn o ti ipà idà ṣubu ninu rẹ̀, li Oluwa Ọlọrun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Èyí yìí ní OLÚWA wí: “ ‘Àwọn alejò Éjíbítì yóò ṣubú agbára ìgbéraga rẹ yóò kùnà láti Mígídólì títí dé Ásúwánì wọn yóò ti ipa idà ṣubú láàárin rẹ; ní OLÚWA Ọlọ́run wí: