Ezekiel 30:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nígbà tó bá tó àkókò, n óo rán àwọn ikọ̀ ninu ọkọ̀ ojú omi, wọn ó lọ dẹ́rù ba àwọn ará Etiopia tí wọn ń gbé láìfura. Wahala yóo dé bá àwọn ará Etiopia ní ọjọ́ ìparun Ijipti. Wò ó, ìparun náà ti dé tán.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ na ni onṣẹ yio lọ lati ọdọ mi ninu ọkọ̀, lati dẹ̀ruba Etiopia ti o wà li alafia, irora yio wá sori wọn gẹgẹ bi li ọjọ Egipti: kiyesi i, o de.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ní ọjọ́ náà oníṣẹ́ yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde nínú ọkọ̀ ojú omi láti dẹ́rùbà Kúsì kúrò nínú ìtẹ́lọ́rùn rẹ̀. Ìrora yóò wá sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ ìparun Éjíbítì: Kíyèsí i, ó dé.