Ezekiel 31:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn àjèjì láti inú orílẹ̀-èdè, tí ó burú jùlọ, yóo gé e lulẹ̀, wọn yóo sì fi í sílẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóo bọ́ sílẹ̀ lórí àwọn òkè ati ní àwọn àfonífojì, igi rẹ̀ yóo sì wà nílẹ̀ káàkiri ní gbogbo ipadò ilẹ̀ náà. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo kúrò lábẹ́ òjìji rẹ̀, wọn yóo sì fi sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn alejo, ẹlérù awọn orilẹ-ède, ti ké e kuro, nwọn si ti tú u ká; ẹka rẹ̀ ṣubu sori awọn oke, ati ninu gbogbo afonifoji, ẹka rẹ̀ si ṣẹ́ lẹba gbogbo odò ilẹ na; gbogbo awọn orilẹ-ède aiye si jade lọ kuro labẹ òjiji rẹ̀, nwọn si fi i silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
àwọn orílẹ̀ èdè àjòjì aláìláàánú jùlọ ké e lulẹ̀, wọn sì fi kalẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ṣubú sórí òkè àti sí gbogbo àárin àwọn òkè; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tí ó ṣẹ nà sílẹ̀ ní gbogbo àlàfo jíjìn ilẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè ilẹ̀ ayé jáde kúrò ní abẹ́ ìjì rẹ̀ wọn sì fi sílẹ̀.