Ezekiel 31:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo èyí yóo ṣẹlẹ̀ kí igi mìíràn tí ó bá wà lẹ́bàá omi náà má baà ga fíofío mọ́, tabi kí orí rẹ̀ wọ inú ìkùukùu ní ojú ọ̀run. Kò sì ní sí igi tí ń fa omi, tí yóo ga tó ọ; nítorí gbogbo wọn ni wọn óo kú, tí wọn óo sì lọ sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun ilẹ̀ bí àwọn alààyè eniyan tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ki igikigi ti o wà lẹba omi ki o má ba gbe ara wọn ga nitori giga wọn, tabi ki nwọn yọ ṣonṣo wọn lãrin ẹ̀ka dídi; tabi ki igi wọn duro ni giga wọn, gbogbo awọn ti o mu omi: nitori ti a fi gbogbo wọn le ikú lọwọ, si isalẹ aiye, li ãrin awọn ọmọ enia, pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà kò sí igi mìíràn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tí ó lè fi ìgbéraga ga sókè fíofío, tí yóò sì gbé sókè rẹ̀ ga ju ewé tí ó nípọn lọ. Kò sí igi mìíràn tí ó ní omi tó bẹ́ẹ̀ tí ó lè ga tó bẹ́ ẹ̀; gbogbo wọn ni a kádàrá ikú fún, fún ìsàlẹ̀ ilẹ̀, ní àárin àwọn alààyè ènìyàn, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ọ̀gbun ní ìsàlẹ̀.