Ezekiel 31:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun ní: “Nígbà tí ó bá wọ isà òkú ọ̀gbun ilẹ̀ pàápàá, n óo ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, n óo sé àwọn odò n óo sì ti orísun omi ìsàlẹ̀ ilẹ̀ nítorí rẹ̀, òkùnkùn óo bo Lẹbanoni, gbogbo igi inú igbó yóo gbẹ nítorí rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; pe, Li ọjọ ti o sọkalẹ lọ si ibojì mo jẹ ki ọ̀fọ ki o wà, mo fi ibú bò o mọlẹ, mo si se awọn iṣàn omi, awọn omi nla ni mo si dá duro: emi si jẹ ki Lebanoni ki o ṣọ̀fọ fun u, gbogbo igi igbẹ́ si dakú nitori rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Èyí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: ní ọjọ́ ti a mú u wá sí isà òkú mo fi ọ̀fọ̀ ṣíṣe bo orísun omi jínjìn náà; Mo dá àwọn ìṣàn omi rẹ̀ dúró, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi rẹ̀ ní a dí lọ́nà. Nítorí rẹ̀ mo fi ìwúwo ọkàn wọ Lẹ́bánónì ní aṣọ, gbogbo igi ìgbẹ́ gbẹ dànù.