Ezekiel 31:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìró wíwó rẹ̀ yóo mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì. Nígbà tí mo bá wó o lulẹ̀ tí mo bá sọ ọ́ sinu isà òkú pẹlu àwọn tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú; gbogbo àwọn igi Edẹni, ati àwọn igi tí wọ́n dára jù ní Lẹbanoni, gbogbo àwọn igi tí ń rí omi mu lábẹ́ ilẹ̀ ni ara yóo tù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi mu awọn orilẹ̀-èdè mì nipa iró iṣubu rẹ̀, nigbati mo sọ ọ sinu ipòokú, pẹlu awọn ti o sọkalẹ sinu ihò, ati gbogbo igi Edeni, awọn àṣayan ati awọn ti o dara jù ti Lebanoni, gbogbo awọn ti o mu omi, li a o tù ninu ni ìsalẹ aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo mú kí orílẹ̀ èdè wárìrì sì ìró ìṣubú rẹ̀ nígbà tí mo mú un wá sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun ìṣàlẹ̀. Nígbà náà gbogbo igi Édẹ́nì, àṣàyàn àti èyí tí ó dára jùlọ nínú Lẹ́bánónì, gbogbo igi tí ó ní omi dáadáa ni a tù nínú ni ayé ìsàlẹ̀.