Ezekiel 31:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ògo ati títóbi ta ni a lè fi wé tìrẹ láàrin àwọn igi tí ó wà ní Edẹni? Ṣugbọn a óo gé ọ lulẹ̀ pẹlu àwọn igi ọgbà Edẹni, a óo sì wọ́ ọ sọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀. O óo wà nílẹ̀ láàrin àwọn aláìkọlà, pẹlu àwọn tí a fi idà pa. Farao ati ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ni mò ń sọ nípa wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tani iwọ jọ li ogo ati ni titobi lãrin awọn igi Edeni? sibẹ a o mu ọ wá ilẹ pẹlu awọn igi Edeni si ìsalẹ aiye, iwọ o dubulẹ li ãrin awọn alaikọlà, pẹlu awọn ti a fi idà pa. Eyi ni Farao ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀, li Oluwa Ọlọrun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Èwo lára igi Édẹ́nì ní a lè fi wé ọ ní dídán àti ọlá ńlá? Síbẹ̀ ìwọ, gan an wá sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn igi Édẹ́nì lọ sí ìṣàlẹ̀ ilẹ̀; ìwọ yóò sùn ni àárin àwọn aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa. “ ‘Èyí yìí ní Fáráò àti ìjọ rẹ̀, ní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.’ ”