Ezekiel 31:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Igi kedari tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun kò lè farawé e. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ka igi firi kò sì tó ẹ̀ka rẹ̀. Ẹ̀ka igi kankan kò dàbí ẹ̀ka rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí igikígi ninu ọgbà Ọlọrun tí ó lẹ́wà bíi rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn igi kedari inu ọgbà Ọlọrun kò le bò o mọlẹ: awọn igi firi kò dabi ẹ̀ka rẹ̀, awọn igi kẹsnuti kò si dabi ẹ̀ka rẹ̀; bẹ̃ni kò si igikigi ninu ọgbà Ọlọrun ti o dabi rẹ̀ li ẹwà rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn òpépé igi nínú ọgbà Ọlọ́run kò lè è bá a dọ́gba, tàbí kí àwọn igi firi ṣe déédé pẹ̀lú ẹ̀ka rẹ̀, tàbí kí a fi igi títẹ́ rẹrẹ wé ẹ̀ka rẹ̀, kò sí igi nínú ọgbà Ọlọ́run tí ẹwà rẹ̀ ṣe déédé pẹ̀lú rẹ̀.