Ezekiel 32:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo jẹ́ kí ẹnu ya ọpọlọpọ eniyan nítorí yín, àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì wárìrì nítorí tiyín, nígbà tí mo bá ń fi idà mi lójú wọn, olukuluku wọn óo máa wárìrì nígbàkúùgbà nítorí ẹ̀mí ara rẹ̀, ní ọjọ́ ìṣubú rẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitõtọ, emi o mu ki ẹnu yà ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède si ọ, awọn ọba wọn yio si bẹ̀ru gidigidi nitori rẹ, nigbati emi o ba mì idà mi niwaju wọn; nwọn o si warìri nigbagbogbo, olukuluku enia fun ẹmi ara rẹ̀, li ọjọ iṣubu rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn dẹ́rù bà ọ́, àwọn Ọba wọn yóò sì wárìrì fún ìbẹ̀rù pẹ̀lú ìpayà nítorí rẹ, nígbà tí mo bá ju idà mi ní iwájú wọn Ní ọjọ́ ìṣubú rẹ ìkọ̀ọ̀kan nínú wọn yóò wárìrì ní gbogbo ìgbà fún ẹ̀mí rẹ.