Ezekiel 32:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo wá àwọn alágbára, àwọn tí wọ́n burú jùlọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo jẹ́ kí gbogbo wọn fi idà pa ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ. Wọn yóo sọ ìgbéraga Ijipti di asán, ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ yóo sì parun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o mu ki ọ̀pọlọpọ enia rẹ ṣubu nipa idà awọn alagbara, ẹlẹ́rù awọn orilẹ-ẹ̀de ni gbogbo wọn; nwọn o si bà afẹ́ Egipti jẹ́, ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ ni nwọn o parun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò mú kí ìjọ ènìyàn rẹ kí ó tí ipa idà àwọn alàgbà ènìyàn ṣubú àwọn orílẹ̀ èdè aláìláàánú jùlọ. Wọn yóò tú ìgbéraga Éjíbítì ká, gbogbo ìjọ rẹ ní a óò dá ojú wọn bolẹ̀.