Ezekiel 32:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí mo bá sọ ilẹ̀ Ijipti di ahoro, tí mo bá pa gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ run; tí mo bá pa gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ run, wọn yóo mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati emi o mu ki ilẹ Egipti di ahoro ti ilẹ na yio si di alaini ohun ti o kún inu rẹ̀ ri, nigbati emi o kọlù gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀, nigbana ni nwọn o mọ̀ pe emi li Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí mo bá sọ Éjíbítì di ahoro, tí mo sì kó gbogbo ohun tí ó wà ní orí ilẹ̀ náà kúrò. Nígbà tí mo bá gé àwọn olùgbé ibẹ̀ lulẹ̀, nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA.’