Ezekiel 32:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn eniyan yóo máa kọ ọ̀rọ̀ yìí ní orin arò; àwọn ọmọbinrin ní àwọn orílẹ̀-èdè ni yóo máa kọ ọ́. Wọn óo máa kọ ọ́ nípa Ijipti ati ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀. Èmi, OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eyi ni ohùn-rére, nwọn o si pohùnrére rẹ̀: awọn ọmọbinrin awọn orilẹ-ède yio pohùnrére rẹ̀: nwọn o pohùnrére nitori rẹ̀, ani fun Egipti, ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀, li Oluwa Ọlọrun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èyí yìí ni ẹkún tí a óò sun fún un. Àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀ èdè yóò sun ún; nítorí Éjíbítì àti gbogbo ìjọ rẹ, wọn yóò sun ún, ní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.”