Ezekiel 32:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lórí ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan Ijipti, rán àwọn ati àwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́lá yòókù lọ sinu isà òkú, sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ti fi ilẹ̀ bora.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ enia, pohùnrére fun ọ̀pọlọpọ enia Egipti, ki o si sọ̀ wọn kalẹ, on, ati awọn ọmọbinrin orilẹ-ède olokiki, si ìsalẹ aiye, pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ sinu ihò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún ìjọ Éjíbítì kí o sì ránsẹ́ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ àti òun àti àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀ èdè alágbára, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ìsàlẹ̀, kòtò.