Ezekiel 32:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, gbé ohùn sókè kí o kọ orin arò nípa Farao, ọba Ijipti. Wí fún un pé ó ka ara rẹ̀ kún kinniun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. Ṣugbọn ó dàbí diragoni ninu omi. Ó ń jáde tagbára tagbára láti inú odò, ó ń fẹsẹ̀ da omi rú, ó sì ń dọ̀tí àwọn odò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ enia, pohunrére fun Farao ọba Egipti, si wi fun u pe, Iwọ dabi ẹgbọ̀rọ kiniun awọn orilẹ-ède, iwọ si dabi dragoni ninu okun, iwọ si jade wá pẹlu awọn odò rẹ, iwọ ti fi ẹsẹ rẹ rú omi, o si ti bà awọn odò wọn jẹ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọmọ ènìyàn, ṣe ìpohùnréré ẹkún nítorí Fáráò Ọba Éjíbítì kí o sì wí fún un: “ ‘Ìwọ dàbí kìnnìún láàárin àwọn orílẹ̀ èdè náà; ìwọ dàbí ohun abanilẹ́rù inú àwọn okun to ń lọ káàkiri inú àwọn odò rẹ, ìwọ fi ẹsẹ rẹ tẹ omi láti mú kí àwọn odò ní ẹrẹ̀.