Ezekiel 32:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ibojì rẹ̀ wà ní ìpẹ̀kun isà òkú. Ibojì àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì tò yí tirẹ̀ ká. Àwọn tí ń dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láyé, gbogbo wọn ni wọ́n ti kú ikú ogun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ibojì awọn ẹniti a gbe kà ẹgbẹ́ ihò, awọn ẹgbẹ́ rẹ̀ si yi ibojì rẹ̀ ka, gbogbo wọn li a pa, nwọn ti ipa idà ṣubu, ti o da ẹ̀ru silẹ ni ilẹ alãye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Isà òkú wọn wà ní ibi tí ó jìnlẹ̀ gan an nínú kòtò. Gbogbo àwọn tí ó ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè ní a pa, tí ó ti ipa idà ṣubú.