Ezekiel 32:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n tẹ́ ibùsùn fún Elamu láàrin àwọn tí wọ́n kú sójú ogun pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀. Ibojì wọn yí tirẹ̀ ká, gbogbo wọn ni a fi idà pa láìkọlà abẹ́. Wọ́n ń dẹ́rù ba àwọn eniyan nígbà tí wọ́n wà láàyè. Wọ́n fi ìtìjú wọlẹ̀ lọ, wọ́n lọ bá àwọn tí wọ́n wà ní ipò òkú. A kó gbogbo wọn pọ̀ mọ́ àwọn tí wọ́n kú sójú ogun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn ti gbe akete kan kalẹ fun u li ãrin awọn ti a pa pẹlu gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀: awọn ibojì rẹ̀ yi i ka, gbogbo wọn alaikọla ti a fi idà pa: bi a tilẹ dá ẹ̀ru wọn silẹ ni ilẹ alãye, sibẹ nwọn ti rù itiju wọn pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò: a fi i si ãrin awọn ti a pa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A ṣe ibùsùn fún un láàárin àwọn tí a pa, pẹ̀lú gbogbo ìjọ rẹ̀ tí ó yí isà òkú ká. Gbogbo wọn jẹ́ aláìkọlà, tí a fi idà pa. Nítorí pé a tan ẹ̀rù wọn ká ilẹ̀ alààyè, wọn ru ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò; a tẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn tí a pa.