Ezekiel 32:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Meṣeki ati Tubali wà níbẹ̀ pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan wọn. Ibojì wọn yí ibojì rẹ̀ ká, gbogbo wọn ni wọ́n kú lójú ogun ní aláìkọlà. Nítorí wọ́n ń dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láàyè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Meṣeki ati Tubali wà nibẹ, ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀: awọn ibojì rẹ̀ yi i ka: gbogbo wọn alaikọlà ti a fi idà pa, bi nwọn tilẹ dá ẹ̀ru wọn silẹ ni ilẹ alãye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Méṣékì àti Túbálì wà níbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìjọ wọn yí isà òkú wọn ká. Gbogbo wọn jẹ́ aláìkọlà, wọ́n fi idà pa wọ́n nítorí ẹ̀rù ti wọn tàn ká ilẹ̀ alààyè.