Ezekiel 32:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn kò sin wọ́n bí àwọn alágbára tí wọ́n wà ní àtijọ́ tí wọ́n sin sí ibojì pẹlu ohun ìjà ogun wọn lára wọn: àwọn tí a gbé orí wọn lé idà wọn, wọ́n sì fi asà wọn bo egungun wọn mọ́lẹ̀; nítorí àwọn alágbára wọnyi dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láàyè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn kì yio si dubulẹ tì awọn alagbara ti o ṣubu ninu awọn alaikọlà, ti nwọn sọkalẹ lọ si ipò-okú pẹlu ihámọra ogun wọn: nwọn ti fi idà wọn rọ ori wọn, ṣugbọn aiṣedẽde wọn yio wà lori egungun wọn, bi nwọn tilẹ jẹ ẹ̀ru awọn alagbara ni ilẹ alãye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣé wọn kò sùn pẹ̀lú àwọn ọ̀gágun aláìkọlà tí ó ti ṣubú, tí o lọ sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú ohun ìjà, tí a sì fi idà wọn sí ìgbérí wọn? Ìjìyà fún ẹ̀sẹ̀ wọn sinmi ní orí egungun wọn, ẹ̀rù àwọn ọ̀gágun ti wà káàkiri ilẹ̀ alààyè.