Ezekiel 32:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Edomu náà wà níbẹ̀ pẹlu àwọn ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀. Bí wọ́n ti lágbára tó, wọ́n sùn pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun. Wọ́n sùn pẹlu àwọn aláìkọlà, pẹlu àwọn tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Edomu wà nibẹ, awọn ọba rẹ̀, ati awọn ọmọ-alade rẹ̀, ti a tẹ́ pẹlu agbara wọn tì awọn ti a fi idà pa, nwọn o dubulẹ tì awọn alaikọlà, ati pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Édómù wà níbẹ̀, àwọn Ọba rẹ̀ àti gbogbo ọmọbìnrin Ọba; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní agbára, a tẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa. Wọn dùbúlẹ̀ pẹ̀lú aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn ti o lọ sínú kòtò.