Ezekiel 32:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Sọ pé èmi, OLUWA Ọlọrun ní n óo da àwọ̀n mi bò ó níṣojú ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan; wọn óo sì fi àwọ̀n mi wọ́ ọ sókè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitorina emi o nà àwọn mi sori rẹ pẹlu ẹgbẹ́ enia pupọ̀; nwọn o si fà ọ goke ninu àwọn mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Èyí yìí ńi OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: “ ‘Pẹ̀lu ọ̀pọ̀ ìpéjọ ènìyàn Èmi yóò da àwọ̀n mi bò ọ́ wọn yóò sì fà ọ́ sókè nínú àwọ̀n mi.