Ezekiel 32:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Gbogbo àwọn olórí láti apá àríwá wà níbẹ̀, ati gbogbo àwọn ará Sidoni, tí wọ́n fi ìtìjú wọlé lọ sí ipò òkú pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lo agbára wọn láti dẹ́rù bani, wọ́n sùn láìkọlà, pẹlu ìtìjú, pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun. Pẹlu àwọn tí wọ́n lọ sinu isà òkú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ-alade ariwa wà nibẹ, gbogbo wọn, ati awọn ara Sidoni, ti nwọn sọkalẹ lọ pẹlu awọn ti a pa; pẹlu ẹ̀ru wọn, oju agbara wọn tì wọn; nwọn si dubulẹ li alaikọlà pẹlu awọn ti a fi idà pa, nwọn si rù itiju wọn pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Gbogbo àwọn ọmọ aládé ilẹ̀ àríwá àti gbogbo àwọn ará Sídónì wà níbẹ̀; wọn lọ sí ìsàlẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí a pa ní ìtìjú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ṣe okùnfà ẹ̀rù pẹ̀lú agbára wọn. Wọn sùn ní àìkọlà pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa, wọn sì ru ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò.