Ezekiel 32:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“N óo jẹ́ kí ọkàn ọpọlọpọ eniyan dààmú nígbà tí mo bá ko yín ní ìgbèkùn lọ sí ilẹ̀ tí ẹ kò dé rí, láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si bí ọ̀pọlọpọ enia ninu, nigbati emi o ba mu iparun rẹ wá sãrin awọn orilẹ-ède, si ilẹ ti iwọ kò ti mọ̀ ri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò da ọkàn ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn rú nígbà tí mo bá mú ìparun rẹ wá ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwọ kò í tí ì mọ̀.