Ezekiel 33:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé mo gbọ́ ohun tí wọn ń sọ pé, ‘Àìdára wa ati ẹ̀ṣẹ̀ wa wà lórí wa, a sì ń joró nítorí wọn; báwo ni a óo ṣe yè?’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, iwọ ọmọ enia, sọ fun ile Israeli; pe, Bayi li ẹnyin nwi, pe, Bi irekọja ati ẹ̀ṣẹ wa ba wà lori wa, ti awa si njoró ninu wọn, bawo li a o ti ṣe le wà lãye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọmọ ènìyàn; sọ fún ilé Ísírẹ́lì, ‘Èyí yìí ní ìwọ sọ: “Àwọn ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ wa tẹ orí wa ba, àwa sì ń sòfò dànù nítorí wọn. Bá wó wa ni a ṣe lè yè?” ’