Ezekiel 33:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wí fún wọn pé èmi OLUWA ní, mo fi ara mi búra pé inú mi kò dùn sí ikú eniyan burúkú, ohun tí mo fẹ́ ni pé kí ó yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ó sì yè. Ẹ yipada! Ẹ yipada kúrò ninu iṣẹ́ ibi yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, kí ló dé tí ẹ fi fẹ́ kú?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sọ fun wọn pe, Bi emi ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, emi kò ni inu-didun ni ikú enia buburu, ṣugbọn ki enia buburu yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀ ki o si yè: ẹ yipada, ẹ yipada kuro ninu ọ̀na buburu nyin; nitori kini ẹnyin o ṣe kú, Ile Israeli?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ fún wọn pé, ‘Níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, èmi kò ní inú dídùn sí ikú ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, kí wọ̀nyí padà kúrò ní ọ̀nà wọn gbogbo kì wọn kì ó sì yè. Yí! Yípadà kúrò ni ọ̀nà búburú gbogbo! Kí ló dé tí ìwọ yóò kú Áà! Ísírẹ́lì?’