Ezekiel 33:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ìwọ ọmọ eniyan, wí fún àwọn eniyan rẹ pé, bí olódodo bá dẹ́ṣẹ̀ ìwà òdodo rẹ̀ kò ní gbà á là, bẹ́ẹ̀ sì ni bí eniyan burúkú bá yí ìwà rẹ̀ pada, kò ní kú nítorí ìwà burúkú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni bí olódodo bá dẹ́ṣẹ̀, kò ní yè nítorí òdodo rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, iwọ ọmọ enia, sọ fun awọn ọmọ enia rẹ, ododo olododo kì yio gbà a là li ọjọ irekọja rẹ̀: bi o ṣe ti ìwa buburu enia buburu, on kì yio ti ipa rẹ̀ ṣubu li ọjọ ti o yipada kuro ninu ìwa buburu rẹ̀: bẹ̃ni olododo kì yio là nipa ododo rẹ̀ li ọjọ ti o dẹṣẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, sọ fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ rẹ, ‘Ìsòdodo ti olódodo ènìyàn kì yóò gbà á nígbà tí òun bá ṣe àìgbọ́ràn, ìwà búburú ènìyàn búburú kì yóò mú kí o ṣubú nígbà tí ó bá yí padà kúrò nínú rẹ̀. Bí olódodo ènìyàn bá ṣẹ̀, a kò ni jẹ́ kí ó yè nítorí òdodo rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀.’