Ezekiel 33:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo wí fún olódodo pé yóo yè, bí ó bá gbójú lé òdodo ara rẹ̀, tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, n kò ní ranti ọ̀kankan ninu ìwà òdodo rẹ̀, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati emi o wi fun olododo pe, yiyè ni yio yè, bi o ba gbẹkẹle ododo ara rẹ̀, ti o si ṣe aiṣedẽde, gbogbo ododo rẹ̀ li a kì yio ranti mọ, ṣugbọn nitori aiṣedẽde ti o ti ṣe, on o ti itori rẹ̀ kú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí mo bá sọ fún olódodo ènìyàn pé òun yóò yè, ṣùgbọ́n nígbà náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé òdodo rẹ̀ tí ó sì ṣe búburú, a kò ní rántí ìkankan nínú iṣẹ́ òdodo tí o ti ṣe sẹ́yìn; òun yóò kú nítorí búburú tí ó ṣe.