Ezekiel 33:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ìwọ ọmọ eniyan, bá àwọn eniyan rẹ sọ̀rọ̀. Wí fún wọn pé bí mo bá jẹ́ kí ogun jà ní ilẹ̀ kan, tí àwọn eniyan ibẹ̀ bá yan ọ̀kan ninu wọn, tí wọ́n fi ṣe olùṣọ́;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ enia, sọ fun awọn ọmọ enia rẹ, si wi fun wọn pe, Bi emi bá mu idà wá sori ilẹ kan, bi awọn enia ilẹ na bá mu ọkunrin kan ninu ara wọn, ti nwọn si fi ṣe oluṣọ́ wọn:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọmọ ènìyàn sọ̀rọ̀ sí àwọn ènìyàn ilẹ̀ rẹ kí ó sì sọ fún wọn: ‘Nígbà tí mo bá fi idà kọlu ilẹ̀ kan, tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yan ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin wọn láti jẹ́ alóre wọn,