Ezekiel 33:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nítorí náà, wí fún wọn pé OLUWA Ọlọrun ní, Ẹ̀ ń jẹ ẹran pẹlu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀ ń bọ oriṣa, ẹ sì ń pa eniyan, ṣé ẹ rò pé ilẹ̀ náà yóo di tiyín?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, pe, ẹnyin njẹ ẹ̀jẹ mọ ẹran, ẹ si gbe oju nyin soke si awọn oriṣa nyin, ẹ si ta ẹjẹ silẹ, ẹnyin o ha ni ilẹ na?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà sọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin jẹ ẹ̀ran pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ni inú rẹ̀, tí ẹ̀yin sì wó àwọn ère yín, tí ẹ sì ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, Ẹ̀yin yóò ha gba ilẹ̀ náà?