Ezekiel 33:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Idà ni ó kù tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé; ẹ̀ ń ṣe ohun ìríra, ẹ̀ ń bá iyawo ara yín lòpọ̀, ẹ sì rò pé ẹ óo jogún ilẹ̀ yìí?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin gbẹkẹle idà nyin, ẹ ṣe irira, olukuluku nyin bà obinrin aladugbò rẹ̀ jẹ́: ẹnyin o ha ni ilẹ na?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀lé idà yín, ẹ̀yin ṣe nǹkan ìríra, ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú yín baa obìnrin aládúgbò rẹ̀ jẹ́. Ẹ̀yin yóò ha gba ilẹ̀ náà?’