Ezekiel 33:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ń wá sọ́dọ̀ rẹ bí àwọn eniyan tií wá, wọ́n sì ń jókòó níwájú rẹ bí eniyan mi. Wọ́n ń gbọ́ ohun tí ò ń wí, ṣugbọn wọn kò ní ṣe é; nítorí pé ẹnu lásán ni wọ́n fi ń sọ pé wọ́n ní ìfẹ́ pupọ, ṣugbọn níbi èrè tí wọn ó jẹ ni ọkàn wọn wà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si tọ̀ ọ wá, bi enia ti iwá, nwọn si joko niwaju rẹ bi enia mi, nwọn si gbọ́ ọ̀rọ rẹ, ṣugbọn nwọn kì yio ṣe wọn: nitori ẹnu wọn ni nwọn fi nfi ifẹ pupọ hàn, ṣugbọn ọkàn wọn tẹ̀le ojukokoro wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn mi wá sọ́dọ̀ rẹ, gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe ń ṣe, wọn sì jòkòó níwájú rẹ láti fetísí ọ̀rọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò mú wá sí ìṣe. Ẹnu wọn ní wọ́n fí n sọ̀rọ̀ ìfọkànsìn, ṣùgbọ́n ọkàn wọn ní ìwọra èrè tí kò tọ́.