Ezekiel 33:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó gbọ́ ìró fèrè ṣugbọn kò bìkítà, nítorí náà orí ara rẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà. Bí ó bá gbọ́ ìkìlọ̀ ni, kì bá gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O gbọ́ iró ipè, kò si gbà ìkilọ: ẹ̀jẹ rẹ̀ yio wà lori rẹ̀. Ṣugbọn ẹniti o gbọ́ ìkilọ yio gbà ọkàn ara rẹ̀ là.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí tí ó gbọ́ ohùn ìpè ṣùgbọ́n tí kò sì gbọ́ ìkìlọ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní orí ara rẹ̀: Tí ó bá gbọ́ ìkìlọ̀, òun ìbá ti gba ara rẹ̀ là.