Ezekiel 33:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn bí olùṣọ́ bá rí i pé ogun ń bọ̀, tí kò bá fọn fèrè kí ó kìlọ̀ fún àwọn eniyan; bí ogun bá pa ẹnikẹ́ni ninu wọn, ẹni tí ogun pa yóo kú ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn èmi OLUWA óo bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ olùṣọ́ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi oluṣọ́ na bá ri ti idà mbọ̀, ti kò si fun ipè, ti a kò si kìlọ fun awọn enia; bi idà ba de, ti o ba si mu ẹnikẹni lãrin wọn, a mu u kuro nitori aiṣedẽde rẹ̀, ṣugbọn ẹjẹ rẹ̀ li emi o bere lọwọ oluṣọ́ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí alóre bá rí idà ti o ń bọ̀, tí kò sì fọn ìpè láti ki àwọn ènìyàn nílọ̀, tí idà náà wá, tí ó sì gba ẹ̀mí ọ̀kan nínú wọn, a óò mú ọkùnrin náà lọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n èmi yóò bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.’