Ezekiel 33:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí mo bá wí fún eniyan burúkú pé yóo kú, tí o kò sì kìlọ̀ fún un pé kí ó yipada kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀, eniyan burúkú náà yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ọwọ́ rẹ ni n óo ti bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati emi ba wi fun enia buburu pe, Iwọ enia buburu, kikú ni iwọ o kú, bi iwọ kò bá sọ̀rọ lati kìlọ fun enia buburu na ki o kuro li ọ̀na rẹ̀, enia buburu na yio kú nitori aiṣedẽde rẹ̀, ṣugbọn ẹjẹ rẹ̀ li emi o bere li ọwọ́ rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà ti mo bá sọ fún ẹni búburú pé, ‘A! ẹni búburú, ìwọ yóò kú dandan,’ ti ìwọ kò sì sọ̀rọ̀ síta láti yí i lọ́kàn padà kúrò ni ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ẹni búburú náà yóò kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èmi yóò sì bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ.