Ezekiel 33:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn bí ìwọ bá kìlọ̀ fún eniyan burúkú pé kí ó yipada kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀, tí kò sì yipada, yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ìwọ ti gba ẹ̀mí ara tìrẹ là.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn, bi iwọ ba kìlọ fun enia buburu na niti ọ̀na rẹ̀ lati pada kuro ninu rẹ̀, bi on kò ba yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀, on o kù nitori aiṣedẽde rẹ̀, ṣugbọn iwọ ti gbà ọkàn rẹ là.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá kìlọ̀ fún ẹni búburú láti yí padà kúrò ni ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, tí oun kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, òun yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ ti gba ọkàn rẹ̀ là.