Ezekiel 34:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
‘Mo lòdì sí ẹ̀yin olùṣọ́-aguntan, n óo sì bèèrè àwọn aguntan mi lọ́wọ́ yín. N óo da yín dúró lẹ́nu iṣẹ́ olùṣọ́-aguntan, ẹ kò sì ní rí ààyè bọ́ ara yín mọ́. N óo gba àwọn aguntan mi lẹ́nu yín, ẹ kò sì ní rí wọn pa jẹ mọ́.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi dojukọ awọn oluṣọ́ agutan; emi o si bere ọwọ́-ẹ̀ran mi lọwọ wọn, emi o si mu wọn dẹ́kun ati ma bọ́ awọn ọwọ́-ẹran: bẹ̃ni awọn ọluṣọ́ agutan kì yio bọ́ ara wọn mọ, nitori ti emi o gbà ọwọ́-ẹran mi kuro li ẹnu wọn ki nwọn ki o má ba jẹ onjẹ fun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí yìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi ṣe ìlòdì sí àwọn olùsọ́ àgùntàn, èmi yóò sì bèèrè agbo ẹran mi lọ́wọ́ wọn. Èmi yóò sì mú wọn dẹ́kun àti máa darí agbo ẹran mi, tí àwọn olùsọ́ àgùntàn náà kò sì ní lè bọ́ ara wọn mọ́. Èmi yóò gba agbo ẹran mi kúrò ni ẹnu wọn, kì yóò sì jẹ́ oúnjẹ fún wọn mọ́.