Ezekiel 34:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ wò ó! Èmi fúnra mi ni n óo wá àwọn aguntan mi, àwárí ni n óo sì wá wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi, ani emi, o bere awọn agutan mi, emi o si wá wọn ri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Nítorí èyí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi fúnra mi yóò wá àgùntàn mi kiri, èmi yóò sì ṣe àwárí wọn.