Ezekiel 34:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo mú wọn jáde kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, n óo kó wọn jọ láti gbogbo ilẹ̀ ayé, n óo sì kó wọn wá sí ilẹ̀ tiwọn. N óo máa bọ́ wọn lórí àwọn òkè Israẹli, lẹ́bàá orísun omi ati gbogbo ibi tí àwọn eniyan ń gbé ní Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si mu wọn jade kuro ninu awọn orilẹ-ède, emi o si kó wọn jọ lati ilẹ gbogbo, emi o si mu wọn wá si ilẹ ara wọn, emi o si bọ́ wọn lori oke Israeli, lẹba odò, ati ni ibi gbigbé ni ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò mú wọn jáde kúrò ní àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì kó wọn jọ láti inú àwọn ìlú, èmi yóò sì mú wọn wá sí ilẹ ara wọn. Èmi yóò mú wọn jẹ ni orí àwọn òkè gíga Ísírẹ́lì, ni àárin àwọn òkè àti ní gbogbo ibùdó ilẹ̀ náà.