Ezekiel 34:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo fún wọn ní koríko tí ó dára jẹ, orí òkè Israẹli sì ni wọn óo ti máa jẹ koríko. Níbẹ̀, ninu pápá oko tí ó dára ni wọn óo dùbúlẹ̀ sí; ninu pápá oko tútù, wọn yóo sì máa jẹ lórí àwọn òkè Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o bọ́ wọn ni pápa oko daradara ati lori okè giga Israeli ni agbo wọn o wà: nibẹ ni nwọn o dubulẹ ni agbo daradara, pápa oko ọlọ́ra ni nwọn o si ma jẹ lori oke Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò ṣe ìtọ́jú wọn ní pápá oko tútù dáradára, àní orí àwọn òkè gíga ti Ísírẹ́lì ni yóò jẹ́ ilẹ̀ ìjẹ koríko wọ́n. Níbẹ̀ wọn yóò dùbúlẹ̀ ní ilẹ ìjẹ koríko dídára, níbẹ̀ wọn yóò jẹun ní pápá oko tútù tí ó dara ní orí òkè ti Ísírẹ́lì.