Ezekiel 34:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣé kí ẹ máa jẹ oko ninu pápá dáradára kò to yín ni ẹ ṣe ń fi ẹsẹ̀ tẹ àjẹkù yín mọ́lẹ̀? Ṣé kí ẹ mu ninu omi tí ó tòrò kò to yín ni ẹ ṣe fẹsẹ̀ da omi yòókù rú?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ohun kekere ni li oju nyin ti ẹ ti jẹ oko daradara, ṣugbọn ẹnyin si fi ẹsẹ tẹ̀ oko iyokù mọlẹ, ati ti ẹ ti mu ninu omi jijìn, ṣugbọn ẹ si fi ẹsẹ ba eyi ti o kù jẹ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣé oúnjẹ jíjẹ ní pápá oko tútù dídára kò tó yín! Ṣé ó jẹ́ dandan fún ọ láti fi ẹsẹ̀ tẹ pápá oko tútù rẹ tí ó kù? Ṣé omi tí ó tòrò kò tó fún yín ní mímu? Ṣe dandan ni kí ó fi ẹrẹ̀ yí ẹsẹ̀ yín?