Ezekiel 34:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ kí o fi bá àwọn olùṣọ́-aguntan Israẹli wí, fi àsọtẹ́lẹ̀ bá àwọn olórí Israẹli wí pé, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Háà, ẹ̀yin olórí Israẹli tí ẹ̀ ń wá oúnjẹ fún ara yín, ṣé kò yẹ kí olùṣọ́-aguntan máa pèsè oúnjẹ fún àwọn aguntan rẹ̀?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ enia, sọtẹlẹ si awọn oluṣọ́ agutan Israeli, sọtẹlẹ, ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun awọn oluṣọ́ agutan; pe, Egbé ni fun awọn oluṣọ́ agutan Israeli, ti mbọ́ ara wọn, awọn oluṣọ́ agutan kì ba bọ́ ọwọ́-ẹran?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọmọ ènìyàn, fí àsọtẹ́lẹ̀ tako olùsọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì; sọ tẹ́lẹ̀ fún wọn pé: ‘Èyí yìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Ègbé ni fún olùsọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì tí ó ń tọ́jú ara wọn nìkan! Ṣé ó dára kí olùṣọ́ àgùntàn ṣaláì tọ́jú agbo ẹran?