Ezekiel 34:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Igi inú oko yóo máa so; ilẹ̀ yóo sì máa mú ọpọlọpọ irúgbìn jáde. Àwọn eniyan óo máa gbé ilẹ̀ wọn láìléwu, wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ṣẹ́ ọ̀pá àjàgà wọn, tí mo bá sì gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ó kó wọn lẹ́rú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Igi igbẹ́ yio si so eso rẹ̀, ilẹ yio si ma mu asunkun rẹ̀ wá, nwọn o si wà li alafia ni ilẹ wọn, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi o ti ṣẹ́ èdídi àjaga wọn, ti emi o si ti gbà wọn lọwọ awọn ti nwọn nsìn bi ẹrú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn igi ìgbẹ́ yóò mú èso wọn jáde, ilẹ̀ yóò sì mu irúgbìn jáde; A óò sì dá ààbò bo àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ náà. Wọn yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA, nígbà tí mo bá já àwọn ohun tí ó ṣe okùnfà àjàgà, tí mo sì gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ó fi wọ́n ṣe ẹrú.